Translate

Friday 13 November 2015

OLOBE TABI OLOMO

Oro yii je oro kan to ti n jaranpa ranpa nile tipe, nitorina ni mo se ni ki n tete mu so. Oro lori eni to loko, ninu olobe ati olomo.
Gege ba se mo, Yooba feran ounje aladidun, won ki n si fi inu won sere. Won feran omo agaga omokunrin bi kasinkan. Bi iyawo omo won o ba si tete bimo, won a ma gbe igbesi ti ko ni mu aye rogbo fun iru iyawo be.
Okun inu lafin gbe tita, omo gan ole waye bi oko o ba jeun to dun, to mu okan bale. Obinrin to mobe se tio tete bimo san ju eyi to tete bimo tio mobe se. Obe si se yii nikan si ko, itoju ile pelu. Oobun o dara laya, kosi suwon niyawo. Olobe to mo ile tunse, to mo ile toju lo sunwom laya. Olobe n bo wa di olomo sugbon olomo ole pada di olobe lero. Aya to sunwon la o gbe sile o. Olobe lo loko, soko yoko to.

No comments:

LinkWithin

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...