Translate

Showing posts with label Ede ati Asa. Show all posts
Showing posts with label Ede ati Asa. Show all posts

Friday, 13 November 2015

OLOBE TABI OLOMO

Oro yii je oro kan to ti n jaranpa ranpa nile tipe, nitorina ni mo se ni ki n tete mu so. Oro lori eni to loko, ninu olobe ati olomo.
Gege ba se mo, Yooba feran ounje aladidun, won ki n si fi inu won sere. Won feran omo agaga omokunrin bi kasinkan. Bi iyawo omo won o ba si tete bimo, won a ma gbe igbesi ti ko ni mu aye rogbo fun iru iyawo be.
Okun inu lafin gbe tita, omo gan ole waye bi oko o ba jeun to dun, to mu okan bale. Obinrin to mobe se tio tete bimo san ju eyi to tete bimo tio mobe se. Obe si se yii nikan si ko, itoju ile pelu. Oobun o dara laya, kosi suwon niyawo. Olobe to mo ile tunse, to mo ile toju lo sunwom laya. Olobe n bo wa di olomo sugbon olomo ole pada di olobe lero. Aya to sunwon la o gbe sile o. Olobe lo loko, soko yoko to.

Tuesday, 7 July 2015

ERO IBANISORO

Aroko ni ohun ti awon baba wa maa n lo ni aye atijo bi ero ayalukara ode oni. Ohun ni ero ibanisoro Yooba. Won maa n lo lati fi soro asiri, lati fi se ikilo, tabi yo eniyan ninu ewu. O le je ami esin, ise tabi ti egbe. Bi orisirisi aroko se wa bee na ni awon ti a n pa si. Aroko si wa ni lilo ni ode oni sugbon oyato si taye atijo. Un o maa ko nipa aroko ati itumo re fun wa nisin ati ni awon igba miran. Bi a ba fi opa ase ranse si eniyan, itumo re ni pe, oba fe ri lafin. Ti o ba je leyin ti oba ba waja ni a se eyi, itumo re, oba kan eniyan naa. Bi a ba fi ada ati awotele obirin ranse si okunrin, itumo re, ki o fi aya eni ti o fin ranse sile nipa mimu awotele tabi ki o dogun, iyen ti o ba mu ada. Bi a ba fi ewe patan mo ranse si enia, itumo re, ki eni naa ma yan aale Bi a ba fi owo eyo ranse, itumo re, eni ti a ransi a rowo na. Ba fi aso funfun ranse, itumo re, alaafia ni eni ti o fi ranse wa. Ba fi omo ayo ranse, itumo re, ere ni ki eni ti a ransi maa se, ma ja. Ba fi eye iga ti owu lenu ranse, itumo re, ki eni naa fenu mo enu. Ba fi awo ilu ranse, itumo re, won gba eni to fi ranse tayo tayo. Ba fi ewe rekureku ranse, itumo re, eni naa o ni pe dee. Gegebi ati mo a ki n lo pupo ninu awon aroko yii lode oni, mo n ko won lati fi ewa ede ati asa Yoruba han wa, ka si le mo pe ki oyinbo to de ni Yoruba ti n se ohun gbogbo. Yoruba gbon, oyinbo gbon la fi da ile aye.

Thursday, 26 March 2015

IBO DE TAN!!!

Kaabo se daada lo de, ati n reti re o, kaabo se daada lo de. Ibo de tan. Ati duro duro, ati wo ona wo ona. Ibo oun naa lo kun ojo perete yii. Gegebi gbogbo wa ti mo pe ibo gbogbogbo yoo waye ni ojo abameta, e je ki a jade ni opo ka lo dibo fun eniti a mo pe o to fun ise naa. E maa dibo nitori eya tabi esin, e di nitori eni naa lo to fun ise naa. E maa si beru ohunkohun, ibo yii ko ni si ija, aso tabi jagidijagan. Teba ti dibo tan, e koja si ile yin e maa duro ka ibo o! Ojola Naijiria owo wa lowa, PVC pelu ibo wa ni ohun ti a o fi tun se. Fun ojola to dara, e je ka dibo fun iyipada rere. Ibo yii, ibo gbogbo wa ni, agbara wa si ni. E te so ju e, ka le jo je gbadun olojo gbooro. A se se o!!!

Monday, 16 February 2015

SURU; BABA IWA

Yoruba a ma powe 'akanju lowo oju ogun nii lo, ojo ni n o la yoo se ewon, oluwa yoo se te mi yoo roko pe'. Eni fe kanju lowo oju ogun nii lo toto. Nitori eyin iru kikanju bee ki n da rara, yoo si ma gba emi lo ni gba miran. Eni to ni ojo ni oun yoo la, ah ah ah, ewon re ni le, yoo roko oba pe. Nitori ki iru ikan bee to wa si imuse, orisirisi ikan ti o ba ofin ni yoo se nipa se bee a ri ewon eh. Oluwa yoo se te mi, a ro oko pe, ko si iro be sugbon oluwa yoo se ti re ni. Suru baba iwa. Suru ki poju, kosi bi suru ti fe po to ko le poju. Ninu oun gbogbo eje ki a ko bi a tin ni suru nitori suru a maa si ilekun oru rere. Suru lo to ka ma ni!

Saturday, 22 November 2014

MA SE OLE

'Ise ni ogun ise,mura sise ore mi,ise ni afi n di eni giga. Bi a ko ba ri eni feyinti bi ole laa n ri,bi a ko ba ri eni gbekele a tepa mo ise eni. Iya re le lowo ni owo,baba re le ni esin lekan,bi oba gboju le won o te tan ni mo so fun o ......
Oro nla,agboju le ogun fi ara re fun osi ta. Kilode to fi fe sise,oye mi..iya ati baba re lowo bi sekere. Ah o se tepa mo ise ki iwo naa sise fowo ti tode re. Ma je ko wa di nkan abamo fun o ni keyin ooo..... Oro abo laa n so fun omoluabi...

LinkWithin

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...