Translate

Thursday 26 March 2015

IBO DE TAN!!!

Kaabo se daada lo de, ati n reti re o, kaabo se daada lo de. Ibo de tan. Ati duro duro, ati wo ona wo ona. Ibo oun naa lo kun ojo perete yii. Gegebi gbogbo wa ti mo pe ibo gbogbogbo yoo waye ni ojo abameta, e je ki a jade ni opo ka lo dibo fun eniti a mo pe o to fun ise naa. E maa dibo nitori eya tabi esin, e di nitori eni naa lo to fun ise naa. E maa si beru ohunkohun, ibo yii ko ni si ija, aso tabi jagidijagan. Teba ti dibo tan, e koja si ile yin e maa duro ka ibo o! Ojola Naijiria owo wa lowa, PVC pelu ibo wa ni ohun ti a o fi tun se. Fun ojola to dara, e je ka dibo fun iyipada rere. Ibo yii, ibo gbogbo wa ni, agbara wa si ni. E te so ju e, ka le jo je gbadun olojo gbooro. A se se o!!!

No comments:

LinkWithin

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...