Translate

Tuesday, 7 July 2015

ERO IBANISORO

Aroko ni ohun ti awon baba wa maa n lo ni aye atijo bi ero ayalukara ode oni. Ohun ni ero ibanisoro Yooba. Won maa n lo lati fi soro asiri, lati fi se ikilo, tabi yo eniyan ninu ewu. O le je ami esin, ise tabi ti egbe. Bi orisirisi aroko se wa bee na ni awon ti a n pa si. Aroko si wa ni lilo ni ode oni sugbon oyato si taye atijo. Un o maa ko nipa aroko ati itumo re fun wa nisin ati ni awon igba miran. Bi a ba fi opa ase ranse si eniyan, itumo re ni pe, oba fe ri lafin. Ti o ba je leyin ti oba ba waja ni a se eyi, itumo re, oba kan eniyan naa. Bi a ba fi ada ati awotele obirin ranse si okunrin, itumo re, ki o fi aya eni ti o fin ranse sile nipa mimu awotele tabi ki o dogun, iyen ti o ba mu ada. Bi a ba fi ewe patan mo ranse si enia, itumo re, ki eni naa ma yan aale Bi a ba fi owo eyo ranse, itumo re, eni ti a ransi a rowo na. Ba fi aso funfun ranse, itumo re, alaafia ni eni ti o fi ranse wa. Ba fi omo ayo ranse, itumo re, ere ni ki eni ti a ransi maa se, ma ja. Ba fi eye iga ti owu lenu ranse, itumo re, ki eni naa fenu mo enu. Ba fi awo ilu ranse, itumo re, won gba eni to fi ranse tayo tayo. Ba fi ewe rekureku ranse, itumo re, eni naa o ni pe dee. Gegebi ati mo a ki n lo pupo ninu awon aroko yii lode oni, mo n ko won lati fi ewa ede ati asa Yoruba han wa, ka si le mo pe ki oyinbo to de ni Yoruba ti n se ohun gbogbo. Yoruba gbon, oyinbo gbon la fi da ile aye.

No comments:

LinkWithin

Related Posts Plugin for WordPress, Blogger...